1 Chronicles 19:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Joabu ati àwọn ogun Israẹli súnmọ́ àwọn ọmọ ogun Siria láti bá wọn jà, ṣugbọn àwọn ọmọ ogun Siria sá fún wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni Joabu ati awọn enia ti o wà pẹlu rẹ̀ sún siwaju awọn ara Siria si ibi ija: nwọn si sá niwaju rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà Jóábù àti àwọn ọmọ ogun pẹ̀lú Rẹ̀ lọṣíwájú láti lọ jà pẹ̀lú àwọn ará Ṣíríà. Wọ́n sì sálọ kúrò níwájú Rẹ̀.