1 Chronicles 19:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn ará Amoni rí i pé àwọn ará Siria sá, àwọn náà sá fun Abiṣai, wọn sì wọ ìlú wọn lọ. Joabu bá pada sí Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati awọn ọmọ Ammoni si ri pe awọn ara Siria sá, awọn pẹlu sá niwaju Abiṣai arakunrin rẹ̀, nwọn si wọ̀ ilu lọ. Nigbana ni Joabu wá si Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà ti àwọn ará Ámónì ri pé àwọn ará Ṣíríà ń sálọ, àwọn náà sálọ kúrò níwájú arákùnrin Rẹ̀ Ábíṣáì. Wọ́n sì wọ inú ìlú ńlá lọ. Bẹ́ẹ̀ ni Jóábù padà lọ sí Jérúsálẹ́mù.