1 Chronicles 19:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn ará Siria rí i pé àwọn ará Israẹli ṣẹgun àwọn, wọ́n ranṣẹ lọ pe àwọn ọmọ ogun Siria tí wọ́n wà ni ìkọjá odò Yufurate, wọ́n sì fi wọ́n sí abẹ́ Ṣobaki, balogun Hadadeseri.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati awọn ara Siria ri pe a le wọn niwaju Israeli, nwọn ran onṣẹ, nwọn si fà awọn ara Siria ti mbẹ lòke odò: Ṣofaki olori ogun Hadareseri sì ṣiwaju wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ará Ṣíríà rí wí pé àwọn Ísírẹ́lì ti lé wọn, wọ́n rán ìránṣẹ́. A sì mú àwọn ará Ṣíríà rékọjá odò wá, pẹ̀lú Ṣófákì alákóso ọmọ ogun Hádádésérì, tí ó ń darí wọn.