1 Chronicles 19:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Dafidi gbọ́, ó kó gbogbo ọmọ ogun Israẹli jọ, wọ́n rékọjá odò Jọdani, wọ́n lọ dojú kọ ogun Siria, àwọn ọmọ ogun Siria bá bẹ̀rẹ̀ sí bá Dafidi jagun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A si sọ fun Dafidi; on si ko gbogbo Israeli jọ, o si gòke odò Jordani o si yọ si wọn, o si tẹ ogun si wọn. Bẹ̃ni nigbati Dafidi tẹ ogun si awọn ara Siria, nwọn ba a jà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí a sọ fún Dáfídì nípa èyí, ó pe gbogbo Ísírẹ́lì jọ wọ́n sì rékọjá Jódánì; Ó lọ ṣíwájú wọn, ó sì fa ìlà ogun dojúkọ wọ́n. Dáfídì fa ìlà Rẹ̀ láti bá àwọn ará Ṣíríà jagun wọ́n sì doju ìjà kọ ọ́.