1 Chronicles 19:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ogun Siria sá níwájú Israẹli. Dafidi pa ẹẹdẹgbaarin (7,000) àwọn tí wọn ń wa kẹ̀kẹ́-ogun ati ọ̀kẹ́ meji (40,000) ọmọ ogun ẹlẹ́sẹ̀, ó sì pa Ṣobaki olórí ogun Siria.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn ara Siria sá niwaju Israeli, Dafidi si pa ẹ̃dẹgbarin enia ninu awọn ara Siria ti o wà ninu kẹkẹ́, ati ọkẹ-meji ẹlẹsẹ, o si pa Ṣofaki olori ogun na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n wọ́n sálọ kúrò níwájú Ísírẹ́lì, Dáfídì sì pa ẹgbẹ̀rún méje agun-kẹ̀kẹ́ wọn àti ẹgbàá mẹ́rin ọmọ-ogun ẹlẹ́sẹ̀. Ó pa Ṣófákì alákóṣo ọmọ ogun wọn pẹ̀lú.