1 Chronicles 19:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi ní, “N óo fi ìfẹ́ hàn sí Hanuni bí baba rẹ̀ ti fi ìfẹ́ hàn sí mi.” Dafidi bá rán oníṣẹ́ lọ kí i kú àṣẹ̀yìndè baba rẹ̀. Àwọn oníṣẹ́ Dafidi bá lọ sọ́dọ̀ Hanuni ní ilẹ̀ Amoni láti bá a kẹ́dùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si wipe, Emi o ṣe ore fun Hanuni ọmọ Nahaṣi, nitoriti baba rẹ̀ ṣe ore fun mi. Dafidi si ran onṣẹ lati tù u ninu nitori baba rẹ̀. Bẹ̃ni awọn iranṣẹ Dafidi wá si ilẹ awọn ọmọ Ammoni, si ọdọ Hanuni lati tù u ninu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì rò wí pé Èmi yóò fi inú rere hàn sí Hánúnì ọmọ Náháṣì, nítorí baba a Rẹ̀ fi inú-rere hàn sí mi. Bẹ́ẹ̀ ni, Dáfídì rán àwọn aṣojú lọ láti lọ fi ìbákẹ́dùn Rẹ̀ hàn sí Hánúnì níti baba a Rẹ̀. Nígbà tí àwọn ọkùnrin Dáfídì wá sí ọ̀dọ̀ Hánúnì ní ilẹ̀ Àwọn ará Ámónì láti fi ìbákẹ́dùn Rẹ̀ hàn sí i,