1 Chronicles 19:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn àwọn ìjòyè ilẹ̀ Amoni sọ fún ọba pé, “Ṣé o rò pé Dafidi ń bọ̀wọ̀ fún baba rẹ ni ó ṣe rán oníṣẹ́ láti wá bá ọ kẹ́dùn? Rárá o. Ó rán wọn láti wá ṣe amí ilẹ̀ yìí ni, kí ó baà lè ṣẹgun rẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn ijoye awọn ọmọ Ammoni wi fun Hanuni pe, Iwọ rò pe Dafidi bu ọlá fun baba rẹ nitori ti o ran awọn olutunu si ọ? Kò ṣepe awọn iranṣẹ rẹ̀ wá si ọdọ rẹ lati rin wò, ati lati bi ṣubu ati lati ṣe ami ilẹ na?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọkùnrin ọlọ́lá ti Ámónì sọ fún Hánúnì pé, Ṣé ìwọ rò pé Dáfídì ń bu ọlá fún Baba rẹ nípa rírán àwọn ọkùnrin sí ọ láti fi ìbákẹ́dùn Rẹ̀ hàn.? Ṣé àwọn ọkùnrin Rẹ̀ kò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ láti wá kiri àti samí sita orílẹ̀ èdè àti láti bì í ṣubú.