1 Chronicles 19:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, Hanuni mú àwọn oníṣẹ́ Dafidi, ó fá irùngbọ̀n wọn, ó gé ẹ̀wù wọn ní ìbàdí, ó sì lé wọn jáde.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina Hanuni kó awọn iranṣẹ Dafidi, o si fa irungbọn wọn, o si ké agbáda wọn sunmọ ibadi wọn, o ran wọn lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni Hanúnì fi ipá mú àwọn ọkùnrin Dáfídì, fá irun wọn, wọ́n gé ẹ̀wù wọn kúrò ní àárin ìdí Rẹ̀, ó sì rán wọn lọ.