1 Chronicles 19:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ojú tì wọ́n pupọ wọn kò lè pada sílé. Nígbà tí Dafidi gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn, ó ranṣẹ sí wọn pé kí wọ́n dúró sí Jẹriko títí tí irùngbọ̀n wọn yóo fi hù, lẹ́yìn náà kí wọ́n máa pada bọ̀ wá sílé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni awọn kan lọ, nwọn si sọ fun Dafidi bi a ti ṣe awọn ọkunrin na: on si ranṣẹ lọ ipade wọn: nitori oju tì awọn ọkunrin na gidigidi. Ọba si wipe, Ẹ duro ni Jeriko titi irungbọn nyin yio fi hù, nigbana ni ki ẹ si pada wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ẹnìkan wá, tí ó sì sọ fún Dáfídì nípa àwọn ọkùnrin Rẹ̀, ó rán àwọn ìránṣẹ́ láti lọ bá wọn, nítorí wọ́n ti di rírẹ̀ sílẹ̀ gidigidi. Ọba wí pe, Dúró ní Jeríkò títí tí irungbọ̀n yín yóò fi hù, Nígbà náà ẹ padà wá.