1 Chronicles 19:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn ará Amoni rí i pé Dafidi ti kórìíra àwọn, Hanuni ati àwọn eniyan rẹ̀ fi ẹgbẹrun (1,000) talẹnti fadaka ranṣẹ sí Mesopotamia, ati sí Aramu-maaka ati sí Soba, láti yá kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati awọn ọmọ Ammoni ri pe nwọn ti ba ara wọn jẹ lọdọ Dafidi, Hanuni ati awọn ọmọ Ammoni ran ẹgbẹrun talenti fadakà lati bẹ̀wẹ kẹkẹ́ ati ẹlẹsin lati Siria ni Mesopotamia wá, ati lati Siria-Maaka wá, ati lati Soba wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn ará Ámónì rí i wí pé wọ́n ti di ẹ̀ṣẹ̀ ní ihò imú Dáfídì, Hánúnì àti àwọn ará Ámónì rán ẹgbẹ̀rún talẹ́ntì fàdákà láti gba iṣẹ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti àwọn agun-kẹ̀kẹ́ láti síríà Náháráímù, Ṣíríà Mákà àti Ṣóbà.