1 Chronicles 19:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n yá ẹgbaa mẹrindinlogun (32,000) kẹ̀kẹ́ ogun, ati ọba Maaka pẹlu àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n wá, wọ́n sì pàgọ́ ogun wọn sí ẹ̀bá Medeba. Àwọn ará Amoni náà wá kó àwọn ọmọ ogun wọn jọ láti gbogbo ìlú wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni nwọn bẹwẹ ẹgbã mẹrindilogun kẹkẹ́ ati ọba Maaka ati awọn enia rẹ̀; nwọn si wá nwọn si do niwaju Medeba. Awọn ọmọ Ammoni si ko ara wọn jọ lati ilu wọn, nwọn si wá si ogun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n gba iṣẹ́ ẹgbẹ̀rin méjìlélọ́gbọ̀n kẹ̀kẹ́ àti agun-kẹ̀kẹ́ àti ọba Mákà pẹ̀lú àwọn ọ̀wọ́-ọmọ ogun Rẹ̀ tí ó wá pàgọ́ ní ẹ̀bá Médébà, nígbà tí àwọn ará Ámónì kó jọ pọ̀ láti ìlú wọn, tí wọ́n sì jáde lọ fún ogun.