1 Chronicles 2:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn Geṣuri ati Aramu gba Hafoti Jairi lọ́wọ́ rẹ̀, ati Kenati ati àwọn ìletò tí ó wà ní àyíká rẹ̀; gbogbo wọn jẹ́ ọgọta ìlú. Gbogbo wọn jẹ́ arọmọdọmọ Makiri, baba Gileadi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Geṣuri, ati Aramu, gbà ilu Jairi lọwọ wọn, pẹlu Kenati, ati ilu rẹ̀: ani ọgọta ilu. Gbogbo wọnyi ni awọn ọmọ Makiri baba Gileadi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
(Ṣùgbọ́n Gésúrì àti Árámù sì fi agbára gba Hafoti Jáírì, àti Kénátì pẹ̀lú gbogbo agbégbé Rẹ̀ tí wọn tẹ̀dó sí jẹ́ ọgọ́ta ìlú.) Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Mákírì Baba Gílíádì.