1 Chronicles 2:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Juda bí ọmọ marun-un. Batiṣua, aya rẹ̀, ará Kenaani, bí ọmọ mẹta fún un: Eri, Onani ati Ṣela. Eri, àkọ́bí Juda, jẹ́ eniyan burúkú lójú OLUWA, OLUWA bá pa á.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Juda; Eri, ati Onani, ati Ṣela; awọn mẹta yi ni Batṣua, ara Kenaani, bi fun u. Eri, akọbi Juda, si buru loju Oluwa; on si pa a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ Júdà: Érì, Ónánì àti Ṣélà, àwọn mẹ́tẹ̀ta wọ̀nyí ni wọ́n bí fún un láti ọ̀dọ̀ arábìnrin Kénánì, ọmọbìnrin Súà Érì àkọ́bí Júdà, ó sì burú ní ojú OLÚWA; Bẹ́ẹ̀ ni OLÚWA sì pa á.