1 Chronicles 2:55 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ìdílé àwọn akọ̀wé tí wọn ń gbé Jabesi nìyí: àwọn ará Tirati, Ṣimeati, ati Sukati. Àwọn ni ará Keni tí wọ́n ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Hamati baba ńlá wọn ní ilé Rekabu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati idile awọn akọwe ti ngbe Jabesi; awọn ara Tira, awọn ara Ṣimeati, ati awọn ara Sukati. Wọnyi li awọn ara Keni ti o ti ọdọ Hemati wá, baba ile Rekabu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti àwọn ìdílé àwọn akọ̀wé, ẹni tí ń gbé ní Jábésì: àti àwọn ọmọ Tírátì àti àwọn ará Ṣíméátì àti àwọn ará Ṣúkátì. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ará Kénì, ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Hámátì, baba ilé Kélẹ́bù.