1 Chronicles 20:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àkókò òtútù kọjá, ní àkókò tí àwọn ọba máa ń lọ jagun, Joabu gbógun ti ilẹ̀ Amoni; wọ́n dó ti ìlú Raba. Ṣugbọn Dafidi dúró ní Jerusalẹmu. Joabu gbógun ti Raba, ó sì ṣẹgun rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O SI ṣe lẹhin igbati ọdun yipo, li akokò ti awọn ọba lọ si ogun; Joabu si gbé agbara ogun jade, o si ba ilu awọn ọmọ Ammoni jẹ, nwọn si wá, nwọn si do tì Rabba. Ṣugbọn Dafidi duro ni Jerusalemu. Joabu si kọlù Rabba o si pa a run.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àkókò àkọ́rọ̀ òjò, ni ìgbà tí àwọn ọba lọ sí ogun, Jóábù ṣamọ̀nà àwọn ọ̀wọ́ ọmọ ogun. Ó fi ilẹ̀ àwọn ará Ámónì ṣòfò. Ó lọ sí ọ̀dọ̀ Rábà. Ó sì fi ogun dúró tì í. Ṣùgbọ́n Dáfídì dúró sí Jérúsálẹ́mù Jóábù kọlu Rábà, ó sì fi sílẹ̀ ní ìparun.