1 Chronicles 20:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó kó àwọn eniyan tí wọ́n wà ninu ìlú náà, ó sì ń fi wọ́n ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́: Àwọn kan ń lo ayùn, àwọn kan ń lo ọkọ́, àwọn mìíràn sì ń lo àáké. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ṣe sí gbogbo àwọn ìlú Amoni. Òun ati àwọn eniyan rẹ̀ bá pada sí Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si kó awọn enia ti o wà nibẹ jade wá, o si fi ayùn ati irin mimu ati ãke ké wọn. Aní bayi ni Dafidi ṣe si gbogbo ilu awọn ọmọ Ammoni. Ati Dafidi ati gbogbo awọn enia pada bọ̀ si Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì kó gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibẹ̀ jáde, ó sì fi iṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́ láti ṣíṣẹ́ pẹ̀lú ayùn àti ìtulẹ̀ onírin àti àáké. Dáfídì ṣe eléyìí sí gbogbo àwọn ará ìlú Ámónì. Nígbà náà, Dáfídì àti gbogbo àwọn ọmọ ogun Rẹ̀ padà sí Jérúsálẹ́mù.