1 Chronicles 20:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, ogun bẹ́ sílẹ̀ ní Geseri, láàrin àwọn ará Filistia ati àwọn ọmọ Israẹli. Sibekai, ará Huṣati, pa ìran òmìrán kan, ará Filistia, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sipai, àwọn ará Israẹli bá ṣẹgun àwọn ará Filistia.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe lẹhin eyi li ogun si de ni Geseri pẹlu awọn ara Filistia; li akokò na ni Sibbekai ara Huṣa pa Sippai, ti inu awọn ọmọ òmiran: a si tẹ ori wọn ba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ẹ̀yìn èyí ni ogun bẹ́ sílẹ̀ ní Géṣérì pẹ̀lu àwọn ará Fílístínì, ní àkókò yìí ni Ṣíbékíà ará Húsà pa Ṣípáì, ọ̀kan lára àwọn ọmọ Réfáì, àti àwọn ará Fílístínì ni a sẹ́gun.