1 Chronicles 20:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ pẹlu àwọn ará Filistia, Elihanani, ọmọ Jairi, pa Lahimi, arakunrin Goliati, ará Gati, tí ọ̀kọ̀ rẹ̀ tóbi tó òpó òfì ìhunṣọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ogun si tun wà pẹlu awọn ara Filistia; Elhanani ọmọ Jairi si pa Lahamu arakunrin Goliati ara Gati, igi ọ̀kọ rẹ̀ si dabi ìti awunṣọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nínú ogun mìíràn pẹ̀lú àwọn ará Fílístínì, Élíhánánì ọmọ Jáírè pa Láhímì arákùnrin Gòláyátì ará àti, Gátì ẹni ti ó ní ọ̀kọ̀ kan tí ó dàbí ọ̀pá ahunsọ.