1 Chronicles 20:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ ní Gati. Ọkunrin gbọ̀ngbọ̀nràn kan wà níbẹ̀, ìka mẹfa ni ó ní ní ọwọ́ kọ̀ọ̀kan ati ní ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ òmìrán ni òun náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ogun si tun wà ni Gati, nibiti ọkunrin gigun kan gbe wà, ika ati ọmọ-ẹsẹ ẹniti o jẹ mẹrinlelogun, mẹfa li ọwọ kọkan, ati mẹfa li ẹṣẹ kọkan, a si bi i pẹlu fun òmiran.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Síbẹ̀síbẹ̀ ninú ogun mìíràn, tí ó wáyé ní Gátì, ọkùnrin títóbi kan wà tí ó ní ìka mẹ́fà ní ọwọ́ Rẹ̀ pẹ̀lú ìka mẹ́fà ní ẹṣẹ̀ Rẹ̀ (24) Mẹ́rìnlélógún lápapọ̀. Òun pẹ̀lú wá láti Ráfà.