1 Chronicles 21:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
yálà kí ìyàn mú fún ọdún mẹta, tabi kí àwọn ọ̀tá rẹ máa lé ọ kiri, kí wọ́n sì máa fi idà pa yín fún oṣù mẹta, tabi kí idà OLUWA kọlù ọ́ fún ọjọ́ mẹta, kí àjàkálẹ̀ àrùn sọ̀kalẹ̀ sórí ilẹ̀ náà, kí angẹli Ọlọrun sì máa paniyan jákèjádò ilẹ̀ Israẹli. Sọ èyí tí o bá fẹ́, kí n lè mọ ohun tí n óo sọ fún ẹni tí ó rán mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yala ọdun mẹta iyan, tabi iparun li oṣù mẹta niwaju awọn ọta rẹ, ti idà awọn ọta rẹ nle ọ ba; tabi idà Oluwa, ni ijọ mẹta, ani ajakalẹ àrun ni ilẹ na, ti angeli Oluwa o ma pani ja gbogbo àgbegbe Israeli. Njẹ nisisiyi rò o wò, esi wo ni emi o mu pada tọ̀ ẹniti o ran mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọdún mẹ́ta ìyàn, oṣù mẹ́ta gbígbá lọ niwájú àwọn ọ̀tá rẹ, pẹ̀lú idà wọn láti lé ọ bá, tàbí ọjọ́ mẹ́fà idà OLÚWA ọjọ́ àjàkálẹ̀-àrùn ní ilẹ̀ náà, pẹ̀lú àwọn ángẹ́lì OLÚWA láti pa gbogbo agbègbè Ísírẹ́lì run.’ Nísinsi yìí ǹjẹ́, ronú bí èmi yóò ti ṣe dá ẹni tí ó rán mi lóhùn.”