1 Chronicles 21:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà náà ni Dafidi wí fún Gadi pé, “Ìdààmú ńlá dé bá mi, jẹ́ kí n ṣubú sí ọwọ́ Ọlọrun, nítorí àánú rẹ̀ pọ̀; má jẹ́ kí n bọ́ sí ọwọ́ eniyan.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si wi fun Gadi pe, iyọnu nla ba mi: jẹ ki emi ki o ṣubu si ọwọ Oluwa nisisiyi: nitori ãnu rẹ̀ pọ̀; ṣugbọn má jẹ ki emi ṣubu si ọwọ ẹnia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì wí fún Gádì pé èmi wà nínú ìyọnu ńlá. Jẹ́ kí èmi kí ó ṣubú sí ọwọ́ OLÚWA, nítorí tí àánú Rẹ̀ pọ̀ gidigidi; Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí èmi kí o ṣubú sí ọwọ́ àwọn ènìyàn.