1 Chronicles 21:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọlọrun rán angẹli kan pé kí ó lọ pa Jerusalẹmu run; ṣugbọn bí ó ti fẹ́ pa á run, OLUWA rí i, ó sì yí ọkàn pada, ó wí fún apanirun náà pé, “Ó tó gẹ́ẹ́, dáwọ́ dúró.” Angẹli OLUWA náà bá dúró níbi ìpakà Onani ará Jebusi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọlọrun si ran angeli kan si Jerusalemu lati run u: bi o si ti nrun u, Oluwa wò, o si kãnu nitori ibi na, o si wi fun angeli na ti nrun u pe; O to, da ọwọ rẹ duro. Angeli Oluwa na si duro nibi ilẹ-ipaka Ornani, ara Jebusi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọlọ́run sì rán ańgẹ́lì láti pa Jérúsálẹ́mù run. Ṣùgbọ́n bí áńgẹ́lì ti ń ṣe èyí, OLÚWA sì ríi. Ó sì káàánú nítorí ibi báà, ó sì wí fún áńgẹ́lì tí ó pa àwọn ènìyàn náà run pé, “Ó ti tó! Dá ọwọ́ rẹ dúró.” Ańgẹ́lì OLÚWA náà sì dúró níbi ilẹ̀ ìpakà Áráúnà ará Jébúsì.