1 Chronicles 21:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi rí angẹli náà tí ó dúró ní agbede meji ayé ati ọ̀run, tí ó na idà ọwọ́ rẹ̀ sí orí Jerusalẹmu. Dafidi ati àwọn ìjòyè àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ bá dojúbolẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri angeli Oluwa na duro lagbedemeji aiye ati ọrun, o ni idà fifayọ lọwọ rẹ̀ ti o si nà sori Jerusalemu. Nigbana ni Dafidi ati awọn àgbagba Israeli, ti o wọ aṣọ ọ̀fọ, da oju wọn bolẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì wòkè ó sì rí áńgẹ́lì OLÚWA dúró láàrin ọ̀run àti ayé pẹ̀lú idà fífàyọ ní ọwọ́ Rẹ̀ tí ó sì nàá sórí Jérúsálẹ́mù. Nígbà náà Dáfídì àti àwọn àgbààgbà, sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n sì da ojú wọn bolẹ̀.