1 Chronicles 21:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn Dafidi ọba dá Onani lóhùn pé, “Rárá o, mo níláti ra gbogbo rẹ̀ ní iye tí ó bá tó gan-an ni. N kò ní fún OLUWA ní nǹkan tí ó jẹ́ tìrẹ, tabi kí n rú ẹbọ tí kò ná mi ní ohunkohun sí OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi ọba si wi fun Ornani pe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn emi a rà a ni iye owo rẹ̀ pipe nitõtọ, nitoriti emi kì o mu eyi ti iṣe tirẹ fun Oluwa, bẹ̃ni emi kì o ru ẹbọ-ọrẹ sisun laiṣe inawo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ọba Dáfídì dá Órínánì lóhùn pé, “Rárá, mo wà lórí àti san iye owó rẹ ní pípé, èmi kò sì ní mú fún OLÚWA èyí tí ó jẹ́ tìrẹ, tàbí láti rú ẹbọ ọrẹ sísun tí kò ná mi ní ohun kan.”