1 Chronicles 21:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi tẹ́ pẹpẹ níbẹ̀, ó rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia, ó bá képe OLUWA. OLUWA dá a lóhùn: ó rán iná sọ̀kalẹ̀ láti jó ẹbọ sísun náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si tẹ pẹpẹ kan nibẹ fun Oluwa, o si ru ẹbọ ọrẹ-sisun ati ẹbọ ọpẹ, o si kepe Oluwa; on si fi iná da a li ohùn lati ọrun wá lori pẹpẹ ẹbọ-ọrẹ sisun na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì tẹ́ pẹpẹ fún OLÚWA níbẹ̀ ó sì ní ẹbọ ọrẹ sísun àti ẹbọ ọrẹ àlàáfíà. Ó sì pe orúkọ OLÚWA, OLÚWA sì da lóhùn pẹ̀lú iná láti òkè ọ̀run lórí pẹpẹ fún ẹbọ ọrẹ ṣíṣun.