1 Chronicles 21:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn Joabu dáhùn pé, “Kí Ọlọrun jẹ́ kí àwọn eniyan rẹ̀ pọ̀ síi ní ìlọ́po ìlọ́po lọ́nà ọgọrun-un, ju iye tí wọ́n jẹ́ nisinsinyii lọ! Kabiyesi, ṣebí abẹ́ ìwọ oluwa mi ni gbogbo wọn wà? Kí ló wá dé tí o fi fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀? Kí ló dé tí o fi fẹ́ mú àwọn ọmọ Israẹli jẹ̀bi?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Joabu si wipe, Ki Oluwa ki o mu awọn enia rẹ pọ̀ si i ni igba ọgọrun jù bi wọn ti wà: ọba, oluwa mi, gbogbo wọn kì iha ṣe iranṣẹ oluwa mi? ẽṣe ti oluwa mi fi mbère nkan yi? ẽṣe ti on o fi mu Israeli jẹbi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Jóábù dá a lóhùn pé Kí OLÚWA pọ̀ sí ní ìgbà ọgọ́rùn ún ju ti tẹ́lẹ̀ lọ OLÚWA ọba mi, sé gbogbo wọn kì í ṣe ìránṣẹ́ OLÚWA ni? Kí ni ó dé tí OLÚWA mi ṣe fẹ́ ṣèyí? Kí ni ó de tí yóò fi mú Ísírẹ́lì jẹ̀bi?