1 Chronicles 21:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Joabu fún ọba ní iye àwọn ọkunrin tí wọ́n tó lọ sójú ogun. Wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ marundinlọgọta (1,100,000) ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli, ati ọ̀kẹ́ mẹtalelogun ó lé ẹgbaarun (470,000) ninu àwọn ẹ̀yà Juda.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Joabu si fi apapọ iye awọn enia na fun Dafidi. Gbogbo Israeli jasi ẹgbẹrun ẹgbẹrun ati ọke marun enia ti nkọ idà: Juda si jasi ọkẹ mẹtalelogun le ẹgbãrun ọkunrin ti nkọ idà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jóábù sì sọ iye tí àwọn ajagun ọkùnrin náà jẹ́ fún Dáfídì. Ní gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì jásí ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún àti ọ̀kẹ́ márùn-ún ènìyàn (Mílíọnù kan àti ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ọgọ́rùn-ún) tí ó lè mú idà àti pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́talélógún lé ẹgbàrún ní Júdà.