1 Chronicles 22:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo ti sa gbogbo agbára mi láti tọ́jú ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) talẹnti wúrà kalẹ̀ fún kíkọ́ ilé OLUWA, aadọta ọ̀kẹ́ (1,000,000) talẹnti fadaka, ati idẹ, ati irin tí ó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè wọ̀n. Mo ti tọ́jú òkúta ati pákó pẹlu. O gbọdọ̀ wá kún un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si kiyesi i, ninu ipọnju mi, emi ti pèse fun ile Oluwa na, ọkẹ marun talenti wura, ati ẹgbẹrun ẹgbẹrun talenti fadakà; ati ti idẹ, ati ti irin, laini ìwọn; nitori ọ̀pọlọpọ ni: ati ìti-igi ati okuta ni mo ti pèse; iwọ si le wá kún u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èmi ti gba Ìpọ́nju ńlá láti ṣe fún ile OLÚWA ọ̀kẹ́ márùn ún talẹ́ńtì wúrà, àti ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún talẹ́ntì fàdákà, Ìwọ̀n idẹ àti irin tí ó tóbi àìní ìwọ̀n, àti ìtì igi àti òkúta. Ìwọ sì tún le fi kún wọn.