1 Chronicles 22:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó ní, “Ǹjẹ́ OLUWA Ọlọrun yín kò ha wà pẹlu yín? Ǹjẹ́ kò ti fun yín ní ìfọ̀kànbalẹ̀ káàkiri? Nítorí pé ó ti jẹ́ kí n ṣẹgun gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yìí, ilẹ̀ náà sì wà lábẹ́ àkóso OLUWA ati ti àwọn eniyan rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa Ọlọrun nyin kò ha wà pẹlu nyin? on kò ha ti fi isimi fun nyin niha gbogbo? on sa ti fi awọn ti ngbe ilẹ na le mi li ọwọ; a si ṣẹgun ilẹ na niwaju Oluwa ati niwaju enia rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí pé, “Ṣé kò sí OLÚWA Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú rẹ? Òun kò ha ti fi ìsinmi fún ọ lórí gbogbo ilẹ̀? Nítorí ó sì ti fi àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ náà lé mi lọ́wọ́ ó sì ti fi ìsẹ́gun fún ilẹ̀ náà níwájú OLÚWA àti níwájú àwọn ènìyàn.