1 Chronicles 22:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, ẹ fi tọkàntọkàn wá OLUWA Ọlọrun yín nisinsinyii. Ẹ múra kí ẹ kọ́ ilé ìsìn fún OLUWA Ọlọrun, kí ẹ baà lè gbé Àpótí Majẹmu OLUWA ati gbogbo ohun èlò mímọ́ fún ìsìn Ọlọrun lọ sinu ilé tí ẹ óo kọ́ fún OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi ẹ fi aiya nyin ati ọkàn nyin si atiwá Oluwa Ọlọrun nyin; nitorina dide ki ẹ si kọ́ ibi mimọ́ Oluwa Ọlọrun, lati mu apoti ẹri ti majẹmu Oluwa wọ̀ inu rẹ̀, ati ohun èlo mimọ́ Ọlọrun, sinu ile na ti a o kọ́ fun orukọ Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsìn yìí ẹ sí ọkàn yin payá àti àyà yín sí àti wá OLÚWA Ọlọ́run yín. Bẹ́ẹ̀ sì ni kọ́ ibi mímọ́ fún OLÚWA Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó le gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú OLÚWA àti ohun èlò mímọ́ tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run, sínú ilé OLÚWA tí a o kọ́ fún orúkọ OLÚWA.”