1 Chronicles 22:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pe Dafidi ní, “Tẹmpili tí a óo kọ́ fún OLUWA gbọdọ̀ dára tóbẹ́ẹ̀ tí òkìkí rẹ̀ yóo kàn ká gbogbo ayé; bẹ́ẹ̀ sì ni Solomoni, ọmọ mi, tí yóo kọ́ ilé náà kéré, kò sì tíì ní ìrírí pupọ. Nítorí náà, n óo tọ́jú àwọn ohun èlò sílẹ̀ fún un.” Dafidi bá tọ́jú àwọn nǹkan tí wọn yóo lò sílẹ̀ lọpọlọpọ kí ó tó kú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si wipe, Solomoni ọmọ mi, ọdọmọde ni, o si rọ̀, ile ti a o si kọ́ fun Oluwa, a o si ṣe e tobi jọjọ, fun okiki ati ogo ka gbogbo ilẹ: nitorina emi o pese silẹ fun u. Bẹ̃ni Dafidi si pese silẹ lọ̀pọlọpọ, ki o to kú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì wí pé, Ọmọ mi Sólómónì ọ̀dọ́mọdé ni ó sì jẹ́ aláìní ìríri, ilé tí a ó kọ́ fún OLÚWA gbọdọ̀ jẹ́ títóbi jọjọ, kí ó sì ní òkìkí àti ògo jákèjádò gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè. Nítorí náà ni èmi yóò ṣe pèsè sílẹ̀ fún un. Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì sì ṣe ìpèsè sílẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ kí ó tó di wí pé ó kú.