1 Chronicles 22:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ṣugbọn OLUWA sọ fún mi pé mo ti ta ọpọlọpọ ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, mo sì ti ja ọpọlọpọ ogun; nítorí ọpọlọpọ ìtàjẹ̀sílẹ̀ náà, òun kò ní gbà pé kí n kọ́ tẹmpili òun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe, Iwọ ti ta ẹ̀jẹ silẹ li ọ̀pọlọpọ, iwọ si ti ja ogun nlanla: iwọ kò gbọdọ kọ́ ile fun orukọ mi, nitoriti iwọ ta ẹ̀jẹ pipọ̀ silẹ niwaju mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ mí wá wí pé: ‘Ìwọ ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, o sì ti ja ọ̀pọ̀ ogun ńlá ńlá, kì í ṣe ìwọ ni yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi, nítorí Ìwọ ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ púpọ̀ lórí ilẹ̀ ní ojú mi.