1 Chronicles 22:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní n óo bí ọmọkunrin kan tí ìjọba rẹ̀ yóo jẹ́ ìjọba alaafia, ó ní òun óo fún un ní alaafia, gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ yíká kò sì ní yọ ọ́ lẹ́nu. Solomoni ni orúkọ rẹ̀ yóo máa jẹ́. Ní ìgbà tirẹ̀, Israẹli yóo wà ní alaafia ati àìléwu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i, a o bi ọmọ kan fun ọ, ẹniti yio ṣe enia isimi; emi o si fun u ni isimi lọdọ gbogbo awọn ọta rẹ̀ yika kiri: nitori orukọ rẹ̀ yio ma jẹ Solomoni, emi o si fi alafia ati idakẹjẹ fun Israeli li ọjọ aiye rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ìwọ yóò ní ọmọ tí yóò sì jẹ́ ọkùnrin onírẹ̀lẹ̀ àti onísinmi, Èmi yóò sì fún-un ní ìsinmi láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ọ̀ta Rẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀ yíká. Orúkọ Rẹ̀ yóò sì máa jẹ́ Sólómónì, Èmi yóò sì fi àlàáfíà àti ìdákẹ́jẹ́ fún Ísírẹ́lì lásìkò ìjọba Rẹ̀.