1 Chronicles 23:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Amramu ni Aaroni ati Mose. Aaroni ni a yà sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ibi mímọ́, pé kí òun ati àwọn ìran rẹ̀ títí lae máa sun turari níwájú OLUWA, kí wọ́n máa darí ìsìn OLUWA, kí wọ́n sì máa súre fún àwọn eniyan ní orúkọ rẹ̀ títí lae.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Amramu; Aaroni ati Mose: a si ya Aaroni si ọ̀tọ, ki o le ma sọ awọn ohun mimọ́ jùlọ di mimọ́, on ati awọn ọmọ rẹ̀ lailai, lati ma jo turari niwaju Oluwa, lati ma ṣe iranṣẹ fun u, ati lati ma sure li orukọ rẹ̀ lailai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ Ámírámù. Árónì àti Móṣè. A sì ya Árónì sọ́tọ̀ òun àti àwọn ọmọ Rẹ̀ títí láéláé, láti kọjú sí ohun mímọ́ jùlọ, láti fi rúbọ sísun níwájú OLÚWA, láti máa ṣe òjísẹ́ níwájú Rẹ̀ àti láti kéde ìbùkún ní orúkọ Rẹ̀ títí láéláé.