1 Chronicles 23:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ni baálé baálé ninu ìran Lefi, ní ìdílé ìdílé, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ àwọn tí wọ́n tó ogún ọdún ati jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n dàgbà tó láti ṣiṣẹ́ ninu ilé OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wọnyi ni awọn ọmọ Lefi, bi ile baba wọn; ani olori awọn baba, bi a ti ka wọn ni iye orukọ, nipa ori wọn, awọn ti o ṣiṣẹ ìsin ile Oluwa, lati iwọn ogun ọdun ati jù bẹ̃ lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Léfì bí ìdílé wọn. Olórí ìdílé gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti fi orúkọ sílẹ̀ lábẹ́ orúkọ wọn, ó sì kà wọn ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan, wí pé, àwọn òṣìṣẹ́ tí ó jẹ́ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ń ṣiṣẹ́ ìsìn nínú ilé OLÚWA