1 Chronicles 23:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn iṣẹ́ wọn ni láti máa ran àwọn ọmọ Aaroni lọ́wọ́ ninu iṣẹ́ ìsìn ilé OLUWA, láti máa ṣe ìtọ́jú àgbàlá ati àwọn yàrá ibẹ̀, láti rí i pé àwọn ohun èlò ilé OLUWA wà ní mímọ́, ati láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ mìíràn tí ó yẹ ninu ilé OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori iṣẹ wọn ni lati duro tì awọn ọmọ Aaroni, fun ìsin ile Oluwa, niti àgbala, ati niti iyẹwu, ati niti ṣiṣe ohun èlo wọnni ni mimọ́, ati iṣẹ ìsin ile Ọlọrun;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Iṣẹ́ àwọn ọmọ Léfì ni láti ran àwọn ọmọ Árónì lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ wọn fún ti ilé OLÚWA: láti wà lábẹ́ ìkáwọ́ agbára ìlú, àti ẹ̀gbẹ́ ilé, àti ìwẹ̀nùmọ́ ti gbogbo ohun ìyàsọ́tọ̀ àti ṣíṣe ohun tìí ṣe iṣẹ́ ìsìn nínú ilé OLÚWA.