1 Chronicles 23:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ni wọ́n tún ń ṣe ètò ṣíṣe burẹdi ìfihàn, ìyẹ̀fun fún ẹbọ ohun jíjẹ, àkàrà tí kò ní ìwúkàrà ninu, àkàrà díndín fún ẹbọ, ẹbọ tí a po òróró mọ́, ati pípèsè àwọn oríṣìíríṣìí ìwọ̀n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati fun àkara ifihàn, ati fun iyẹfun kikuna fun ẹbọ ọrẹ, ati fun àkara alaiwu, ati fun eyi ti a yan ninu awo pẹtẹ, ati fun eyi ti a dín, ati fun gbogbo oniruru òṣuwọn ati ìwọn;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì wà ní ìkáwọ́ àkàrà tí wọ́n mú jáde láti orí tábìlì, àti ìyẹ̀fun fún ẹbọ ọrẹ, àti aláìwú pẹ̀tẹ̀, àti fún dídùn àti èyí tí a pòpọ̀, àti gbogbo onírúurú ìwọ̀n àti wíwọ̀n àti òṣùnwọ̀n.