1 Chronicles 24:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n óo ṣe tẹ̀léra wọn níbi iṣẹ́ ṣíṣe ninu ilé OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Aaroni, baba wọn, ti là sílẹ̀ fún wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA Ọlọrun pa fún Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wọnyi ni itò wọn ni ìsin wọn lati lọ sinu ile Oluwa, gẹgẹ bi iṣe wọn nipa ọwọ Aaroni baba wọn, bi Oluwa Ọlọrun Israeli ti paṣẹ fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn wọ̀nyí ni a yàn fún iṣẹ́ ìsìn nígbà tí wọ́n wọ ilé OLÚWA, gẹ́gẹ́ bí ìlànà àti àṣẹ tí a ti fi fún wọn láti ọwọ́ baba ńlá wọn Árónì gẹ́gẹ́ bí OLÚWA, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí pàṣẹ fun wọn.