1 Chronicles 24:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Pẹlu ìrànlọ́wọ́ Sadoku ọmọ Eleasari ati Ahimeleki ọmọ Itamari, Dafidi pín àwọn ọmọ Aaroni sí ẹgbẹẹgbẹ́ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tí wọn ń ṣe ninu iṣẹ́ ìsìn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si pin wọn, ati Sadoku ninu awọn ọmọ Eleasari, ati Ahimeleki ninu awọn ọmọ Itamari, gẹgẹ bi iṣẹ wọn ninu ìsin wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ṣádókì ọmọ Élíásérì àti Áhímélékì ọmọ Ítamárì, Dáfídì sì yà wọ́n nípa nínú ìpín fún ìyàsọ́tọ̀ àwọn iṣẹ́ ìsìn wọn.