1 Chronicles 24:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn olórí ìdílé náà ṣẹ́ gègé gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Aaroni, àwọn arakunrin wọn ti ṣe, níwájú ọba Dafidi, ati Sadoku, ati Ahimeleki, pẹlu àwọn olórí ninu ìdílé alufaa ati ti àwọn ọmọ Lefi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn wọnyi pẹlu ṣẹ keké gẹgẹ bi awọn arakunrin wọn awọn ọmọ Aaroni niwaju Dafidi ọba ati Sadoku, ati Ahimeleki, ati awọn olori awọn baba awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi: olori awọn baba gẹgẹ bi aburo rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì ṣé kèké gẹ́gẹ́ bí àwọn arákùnrin wọn àwọn ọmọ Árónì ṣe ṣẹ́, níwáju ọba Dáfídì àti Ṣádókì, Áhímélékì, àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì. Àwọn ìdilé àgbààgbà arákùnrin wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ lórí àwọn arakùnrin wọn kéékèèkéé.