1 Chronicles 24:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn tí wọ́n jẹ́ baálé baálé pọ̀ ninu àwọn ọmọ Eleasari ju ti Itamari lọ, nítorí náà, wọ́n pín àwọn ọmọ Eleasari sí abẹ́ àwọn baálé baálé mẹrindinlogun, wọ́n sì pín àwọn ọmọ Itamari sí abẹ́ àwọn baálé baálé mẹjọ. Bí wọ́n ṣe pín wọn kò sì fì sí ibìkan nítorí pé
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A si ri awọn ọkunrin ti o nṣe olori ninu awọn ọmọ Eleasari jù ti inu awọn ọmọ Itamari lọ, bayi li a si pin wọn. Ninu awọn ọmọ Eleasari, ọkunrin mẹrindilogun li o nṣe olori ni ile baba wọn, ati mẹjọ ninu awọn ọmọ Itamari, gẹgẹ bi ile baba wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A rí ọ̀pọ̀ àwọn olórí lára àwọn ọmọ Élíásérì ju lára àwọn ọmọ Ítamárì lọ, wọ́n sì pín wọn lẹ́sẹ lẹ́sẹ: mẹ́rindínlógún (16) olórí láti ìdílé ọmọ Élíásérì ìran wọn àti olórí méjọ ìdílé láti ara àwọn ọmọ Ítamárì.