1 Chronicles 24:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
gègé ni wọ́n ṣẹ́ tí wọ́n fi yàn wọ́n, nítorí pé, bí àwọn alámòójútó ìsìn ati alámòójútó iṣẹ́ ilé Ọlọrun ṣe wà ninu àwọn ìran Eleasari, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n wà ninu ti Itamari.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li a fi iṣẹkeké pin wọn, iru kan mọ ikeji pẹlu; nitori awọn olori ibi mimọ́, ati olori ti Ọlọrun wà ninu awọn ọmọ Eleasari, ati ninu awọn ọmọ Itamari.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì pín wọn lótìítọ́ nípa yíya ìpín, nítorí àwọn olórí ibi mímọ́ àti àwọn olorí ilé Ọlọ́run wà láàrin àwọn ọmọ méjèèjì Élíásérì àti Ìtamárì.