1 Chronicles 24:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣemaaya, akọ̀wé, ọmọ Netaneli, láti inú ẹ̀yà Lefi, ni ó kọ orúkọ wọn sílẹ̀ níwájú ọba ati àwọn ìjòyè, ati Sadoku, alufaa, ati Ahimeleki, ọmọ Abiatari, ati àwọn baálé baálé ninu ìdílé àwọn alufaa, ati ti àwọn ọmọ Lefi. Bí wọ́n bá ti mú ọ̀kan láti inú ìran Eleasari, wọn á sì tún mú ọ̀kan láti ìran Itamari.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati Ṣemaiah ọmọ Nataneeli akọwe, ọkan ninu awọn ọmọ Lefi kọ wọn niwaju ọba, ati awọn olori, ati Sadoku alufa, ati Ahimeleki, ọmọ Abiatari, ati niwaju olori awọn baba awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi: a mu ile baba kan fun Eleasari, a si mu ọkan fun Itamari.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣémáíà ọmọ Nétanélì, akọ̀wé ọ̀kan lára àwọn ọmọ Léfì sì kọ orúkọ wọn níwájú ọba àti àwọn ìjòyè: Ṣádókù Àlùfáà, Áhímélékì ọmọ Ábíátarì àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà tí a mú láti ọ̀dọ̀ Éléásári àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ Ítamárì.