1 Chronicles 25:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi ati àwọn olórí ogun ya àwọn kan sọ́tọ̀ ninu àwọn ọmọ Asafu, Hemani ati ti Jedutuni láti máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń fi dùùrù, ati hapu ati aro kọrin. Àkọsílẹ̀ àwọn tí a yàn ati iṣẹ́ wọn nìyí:
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
PẸLUPẸLU Dafidi ati awọn olori ogun yà ninu awọn ọmọkunrin Asafu, ati Hemani, ati Jedutuni, fun ìsin yi, awọn ẹniti o ma fi duru ati psalteri, ati kimbali kọrin: ati iye awọn oniṣẹ gẹgẹ bi ìsin wọn jẹ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pẹ̀lúpẹ̀lú Dáfídì àti àwọn olórí àwọn ọmọ ogun, ó sì yà díẹ̀ sọ́tọ̀ lára àwọn ọmọ Ásáfù, Hémánì àti Jédútúnì fún ìsìn àsọtẹ́lè, pẹ̀lú dùùrù, ohun èlò orin àti kínbálì. Èyí sì ní àwọn iye àwọn ọkùnrin ẹni tí ó ṣe oníṣẹ́ ìsìn yìí: