1 Chronicles 25:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Jedutuni jẹ́ mẹfa: Gedalaya, Seri, ati Jeṣaaya; Ṣimei, Haṣabaya ati Matitaya, abẹ́ àkóso Jedutuni, baba wọn, ni wọ́n wà, wọn a sì máa fi dùùrù sọ àsọtẹ́lẹ̀ ninu orin ọpẹ́ ati ìyìn sí OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ti Jedutuni: awọn ọmọ Jedutuni; Gedaliah, ati Seri, ati Jeṣaiah, Haṣabiah, ati Mattitiah, ati Ṣimei, mẹfa, labẹ ọwọ baba wọn Jedutuni, ẹniti o fi duru kọrin, lati ma dupẹ fun ati lati ma yìn Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gẹ́gẹ́ bí ti Jédútúnì, nínú àwọn ọmọkùnrin Rẹ̀: Gédálià, Ṣérì, Jéṣáíà, Ṣíméhì Háṣábíà àti Mátítíyà, mẹ́fà nínú gbogbo wọn, lábẹ́ ìbojútó baba wọn Jédútúnì, ẹni tí ó sọtẹ́lẹ̀, ẹni tí ó lo dùùrù láti dúpẹ́ àti lati yin OLÚWA: