1 Chronicles 25:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọmọ Hemani, aríran ọba, ni gbogbo wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí Ọlọrun ṣe láti gbé Hemani ga; Ọlọrun fún un ní ọmọkunrin mẹrinla ati ọmọbinrin mẹta.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn wọnyi li awọn ọmọ Hemani, woli ọba ninu ọ̀rọ Ọlọrun, lati ma gbé iwo na soke. Ọlọrun si fun Hemani li ọmọkunrin mẹrinla ati ọmọbinrin mẹta.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Hémánì àti wòlíì ọba. Wọ́n sì fi wọ́n fún nípa ìlérí Ọlọ́run láti máa gbé ìwo sókè. Ọlọ́run sì fún Hémánì ní ọmọkùnrin mẹ́rìnlá àti àwọn ọmọbìnrin mẹ́ta.