1 Chronicles 25:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àpapọ̀ wọn pẹlu àwọn arakunrin wọn, tí a ti kọ́ ní orin kíkọ sí OLUWA, ati lílo ohun èlò orin, jẹ́ ọọdunrun ó dín mejila (288).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni iye wọn, pẹlu awọn arakunrin wọn ti a kọ́ li orin Oluwa, ani gbogbo awọn ti o moye, jasi ọrinlugba o le mẹjọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ìdilé wọn pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó mòye àti àwọn tí a kọ́ ní ohun èlò orin fún OLÚWA, iye wọn sì jẹ́ ọ̀rìnlélúgba ó lé mẹ́jọ (288).