1 Chronicles 26:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣelemaya ni gègé mú fún ẹnu ọ̀nà tí ó wà ní apá ìlà oòrùn. Sakaraya, ọmọ rẹ̀, olùdámọ̀ràn tí ó mòye, ni gègé mú fún ẹnu ọ̀nà ti ìhà àríwá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iṣẹ keké iha ila-õrun bọ̀ sọdọ Ṣelemiah. Nigbana ni nwọn ṣẹ keké fun Sekariah ọmọ rẹ̀, ọlọgbọ́n igbimọ; iṣẹ keké rẹ̀ si bọ si iha ariwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kèké fún ẹnu ọ̀nà ilà oòrùn bọ́ sí ọ̀dọ̀ Ṣélémíáyà, nígbà náà a dá kèké fún ọmọkùnrin rẹ̀ Ṣekaríáyà, ọlọ́gbọ́n onímọ̀ràn, kèké fún ẹnu ọ̀nà àríwá sì bọ́ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.