1 Chronicles 26:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ahija, láti inú ẹ̀yà Lefi, ni ó ń bojútó àwọn ibi ìṣúra tí ó wà ninu ilé OLUWA ati ibi tí wọn ń kó àwọn ẹ̀bùn tí a yà sọ́tọ̀ fún Ọlọrun sí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lati inu awọn ọmọ Lefi, Ahijah li o wà lori iṣura ile Ọlọrun, ati lori iṣura nkan wọnni ti a yà si mimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ẹlẹ́gbẹ́ Léfì wọn wà ní ìdí ilé ìfowópamọ́ sí ti ile Ọlọ́run àti ilé ohun èlò yíyà sọ́tọ̀.