1 Chronicles 26:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣelomiti ati àwọn arakunrin rẹ̀ ni wọ́n ń ṣe ìtọ́jú ẹ̀bùn tí àwọn eniyan bá mú wá, ati àwọn ohun tí wolii Samuẹli, ati Saulu ọba, ati Abineri, ọmọ Neri, ati Joabu, ọmọ Seruaya, ti yà sọ́tọ̀ ninu ilé OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati gbogbo eyiti Samueli, ariran, ati Saulu, ọmọ Kiṣi, ati Abneri ọmọ Neri, ati Joabu ọmọ Seruiah, yà si mimọ́; gbogbo ohun ti a ba ti yà si mimọ́, ohun na mbẹ li ọwọ Ṣelomiti, ati awọn arakunrin rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pẹ̀lú gbogbo nǹkan tí a yà sọ́tọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ṣámúẹ́lì aríranl àti nípasẹ̀ Ṣọ́ọ̀lù ọmọ Kíṣì, Ábínérì ọmọ Nerì àti Joábù ọmọ Ṣeruíà gbogbo ohun tí a yà sọ́tọ̀ sì wà ní abẹ́ ìtọ́jú Ṣélómítì àti àwọn ìbátan Rẹ̀.